43 | GEN 2:12 | (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). |
104 | GEN 4:24 | Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).” |
110 | GEN 5:4 | Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin (800) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
111 | GEN 5:5 | Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú. |
113 | GEN 5:7 | Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
114 | GEN 5:8 | Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú. |
116 | GEN 5:10 | Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. |
117 | GEN 5:11 | Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú. |
119 | GEN 5:13 | Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
120 | GEN 5:14 | Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú. |
122 | GEN 5:16 | Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
123 | GEN 5:17 | Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. |
125 | GEN 5:19 | Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
126 | GEN 5:20 | Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú. |
128 | GEN 5:22 | Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
129 | GEN 5:23 | Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365). |
132 | GEN 5:26 | Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
133 | GEN 5:27 | Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú. |
136 | GEN 5:30 | Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
137 | GEN 5:31 | Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún dín mẹ́tàlélógún (777), ó sì kú. |
138 | GEN 5:32 | Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti. |
153 | GEN 6:15 | Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. |
166 | GEN 7:6 | Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. |
171 | GEN 7:11 | Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. |
197 | GEN 8:13 | Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. |
224 | GEN 9:18 | Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.) |
234 | GEN 9:28 | Noa wà láààyè fún irinwó ọdún dín àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. |
235 | GEN 9:29 | Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín làádọ́ta (950), ó sì kú. |
240 | GEN 10:5 | (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀). |
249 | GEN 10:14 | Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu. |
270 | GEN 11:3 | Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). |
278 | GEN 11:11 | Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
280 | GEN 11:13 | Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. |
282 | GEN 11:15 | Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
284 | GEN 11:17 | Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
286 | GEN 11:19 | Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
288 | GEN 11:21 | Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn. |
299 | GEN 11:32 | Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani. |
329 | GEN 13:10 | Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) |
339 | GEN 14:2 | jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari) jagun. |
340 | GEN 14:3 | Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Siddimu (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀). |
344 | GEN 14:7 | Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (ti o túmọ̀ sí Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú. |
345 | GEN 14:8 | Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu, |
346 | GEN 14:9 | láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). |
351 | GEN 14:14 | Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó lé lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì (318) ènìyàn, ó sì lépa wọn títí dé Dani. |
354 | GEN 14:17 | Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (èyí ni àfonífojì Ọba). |
374 | GEN 15:13 | Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. |
480 | GEN 19:22 | Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari). |
512 | GEN 20:16 | Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún (1,000) owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.” |
532 | GEN 21:18 | Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dìímú (tù ú nínú) nítorí èmi yóò sọ ọmọ náà di orílẹ̀-èdè ńlá.” |
569 | GEN 22:21 | Usi àkọ́bí rẹ̀, Busi arákùnrin rẹ̀, Kemueli (baba Aramu). |
573 | GEN 23:1 | Sara sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádóje (127). |
574 | GEN 23:2 | Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara. |
587 | GEN 23:15 | “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irinwó (400) òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrín àwa méjèèjì? Sá à sin òkú rẹ.” |
588 | GEN 23:16 | Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò. |
591 | GEN 23:19 | Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani. |
633 | GEN 24:41 | Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi (gẹ́gẹ́ bí mo tí wí), nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí.’ |
666 | GEN 25:7 | Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175). |
676 | GEN 25:17 | Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. |
689 | GEN 25:30 | Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu.) |
866 | GEN 30:35 | Ní ọjọ́ náà gan an ni Labani kó gbogbo ewúrẹ́ tí ó ní àmì tàbí ilà (àti òbúkọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgùntàn dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. |
895 | GEN 31:21 | Ó sì sálọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Eufurate), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gileadi. |
935 | GEN 32:7 | Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó (400) ọkùnrin.” |
962 | GEN 33:1 | Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. |
1018 | GEN 35:6 | Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (ti o túmọ̀ sí Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. |
1031 | GEN 35:19 | Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (ti o túmọ̀ sí, Bẹtilẹhẹmu). |
1039 | GEN 35:27 | Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre nítòsí i Kiriati-Arba (ti o túmọ̀ sí Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. |
1049 | GEN 36:8 | Báyìí ni Esau (tí a tún mọ̀ sí Edomu) tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri. |
1060 | GEN 36:19 | Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (ti o túmọ̀ sí Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn. |
1182 | GEN 40:9 | Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, |
1203 | GEN 41:7 | Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni. |
1241 | GEN 41:45 | Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí Safenati-Panea (èyí tí ó túmọ̀ sí ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà). Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já. |
1381 | GEN 45:22 | Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún. |
1395 | GEN 46:8 | Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu. |
1399 | GEN 46:12 | Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. |
1402 | GEN 46:15 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀. |
1449 | GEN 47:28 | Jakọbu gbé ní Ejibiti fún ọdún mẹ́tàdínlógún iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹ́tàdínlàádọ́jọ (147). |
1459 | GEN 48:7 | Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata. Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu). |
1478 | GEN 49:4 | Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀). |
1662 | EXO 6:6 | “Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli, ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá. |
1672 | EXO 6:16 | Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Lefi lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé. |
1674 | EXO 6:18 | Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé. |
1676 | EXO 6:20 | Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un. Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé. |
1727 | EXO 8:12 | Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó ṣì ń ta ni.) |
1774 | EXO 9:31 | (A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi. |
1810 | EXO 11:3 | (Olúwa jẹ́ kí wọn rí ojúrere àwọn ará Ejibiti, pàápàá, Mose fúnra rẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Ejibiti ní iwájú àwọn ìjòyè Farao àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú). |
1854 | EXO 12:37 | Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. |
1857 | EXO 12:40 | Iye ọdún ti àwọn ará Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ejibiti jẹ́ irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430). |
1858 | EXO 12:41 | Ó sì ní òpin irinwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430), ní ọjọ́ náà gan an, ni ó sì ṣe tí gbogbo ogun Olúwa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. |
1872 | EXO 13:4 | Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. |
1897 | EXO 14:7 | ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Ejibiti, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn. |
1944 | EXO 15:23 | Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò. (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò.) |
1984 | EXO 16:36 | (Òsùwọ̀n omeri kan sì jẹ́ ìdákan nínú ìdámẹ́wàá efa.) |
2002 | EXO 18:2 | Nígbà náà ni Jetro mu aya Mose tí í ṣe Sippora padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀), |
2119 | EXO 22:4 | “Bí ọkùnrin kan bá ń bọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lórí pápá tàbí nínú ọgbà àjàrà, tí ó sì jẹ́ kí ó lọ jẹ nínú oko ẹlòmíràn, a ó mú kí ó san ohun ti ẹran rẹ̀ jẹ padà pẹ̀lú èyí tí ó dára jù nínú oko tàbí nínú ọgbà rẹ̀ (ẹlòmíràn padà fún un). |
2238 | EXO 26:2 | Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. |
2282 | EXO 27:9 | “Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù, ó gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mita mẹ́rìndínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, |
2359 | EXO 29:22 | “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́.) |
2406 | EXO 30:23 | “Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kilogiramu mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì, |
2407 | EXO 30:24 | kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lita mẹ́rin). |