119 | GEN 5:13 | Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
280 | GEN 11:13 | Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. |
282 | GEN 11:15 | Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
284 | GEN 11:17 | Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
374 | GEN 15:13 | Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. |
587 | GEN 23:15 | “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irinwó (400) òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrín àwa méjèèjì? Sá à sin òkú rẹ.” |
588 | GEN 23:16 | Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò. |
935 | GEN 32:7 | Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó (400) ọkùnrin.” |
962 | GEN 33:1 | Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. |
1449 | GEN 47:28 | Jakọbu gbé ní Ejibiti fún ọdún mẹ́tàdínlógún iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹ́tàdínlàádọ́jọ (147). |
1857 | EXO 12:40 | Iye ọdún ti àwọn ará Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ejibiti jẹ́ irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430). |
1858 | EXO 12:41 | Ó sì ní òpin irinwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430), ní ọjọ́ náà gan an, ni ó sì ṣe tí gbogbo ogun Olúwa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. |
2663 | EXO 38:29 | Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ǹtì àti egbèjìlá (2,400) ṣékélì. |
3478 | LEV 25:8 | “ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta (49) ni kí ẹ kà. |
3626 | NUM 1:21 | Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500). |
3630 | NUM 1:25 | Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650). |
3632 | NUM 1:27 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600). |
3634 | NUM 1:29 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400). |
3636 | NUM 1:31 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400). |
3638 | NUM 1:33 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). |
3642 | NUM 1:37 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). |
3646 | NUM 1:41 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500). |
3648 | NUM 1:43 | Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). |
3663 | NUM 2:4 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600). |
3665 | NUM 2:6 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400). |
3667 | NUM 2:8 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400). |
3668 | NUM 2:9 | Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ó lé irinwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú. |
3670 | NUM 2:11 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500). |
3674 | NUM 2:15 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650). |
3675 | NUM 2:16 | Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́talélégbèje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì. |
3678 | NUM 2:19 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ó lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). |
3682 | NUM 2:23 | Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). |
3687 | NUM 2:28 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500). |
3689 | NUM 2:30 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé egbèje (53,400). |
3936 | NUM 7:85 | Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin. Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá (2,400) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. |
4244 | NUM 17:14 | Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti pa ẹgbàá méje ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kora. |
4481 | NUM 25:9 | ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000). |
4498 | NUM 26:7 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730). |
4509 | NUM 26:18 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). |
4516 | NUM 26:25 | Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (64,300). |
4532 | NUM 26:41 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600). |
4534 | NUM 26:43 | Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé irinwó (64,400). |
4538 | NUM 26:47 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). |
4541 | NUM 26:50 | Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbèje (45,400). |
5925 | JOS 4:13 | Àwọn bí ọ̀kẹ́ méjì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko láti jagun. |
6633 | JDG 5:8 | Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun, nígbà náà ni ogun wà ní ibodè a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí. |
6877 | JDG 12:6 | wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣibolẹti.’ ” Tí ó bá ní, “Sibolẹti,” torí pé kò ní mọ̀ ọ́n pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) ọkùnrin. |
7058 | JDG 20:2 | Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. |
7073 | JDG 20:17 | Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà. |
7116 | JDG 21:12 | Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani. |
7301 | 1SA 4:2 | Àwọn Filistini mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Israẹli, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Filistini ṣẹ́gun Israẹli wọ́n pa ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin nínú ogun náà. |
7792 | 1SA 22:2 | Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin. |
7877 | 1SA 25:13 | Dafidi sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idà rẹ́ mọ́ ìdí,” olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ̀ mọ́ ìdí; àti Dafidi pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin si gòkè tọ Dafidi lẹ́yìn; igba si jókòó níbi ẹrù. |
7991 | 1SA 30:10 | Ṣùgbọ́n Dafidi àti irinwó (400) ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, tiwọn kò lè kọjá odò Besori sì dúró lẹ́yìn. |
7998 | 1SA 30:17 | Dafidi sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ọjọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irinwó (400) ọmọkùnrin tí wọ́n gun ìbákasẹ tí wọ́n sì sá. |
8261 | 2SA 10:18 | Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀. |
8873 | 1KI 5:6 | Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin. |
8900 | 1KI 6:1 | Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa. |
8979 | 1KI 7:42 | irinwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n; |
9082 | 1KI 9:28 | Wọ́n sì dé Ofiri, wọ́n sì mú irinwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba. |
9108 | 1KI 10:26 | Solomoni sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú ọba ní Jerusalẹmu. |
9363 | 1KI 18:19 | Nísinsin yìí kó gbogbo Israẹli jọ láti pàdé mi lórí òkè Karmeli. Àti kí o sì mú àádọ́ta lé ní irinwó (450) àwọn wòlíì Baali àti irinwó (400) àwọn wòlíì òrìṣà Aṣerah tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jesebeli.” |
9366 | 1KI 18:22 | Nígbà náà ni Elijah wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́ta lé ní irinwó (450) ni wòlíì Baali. |
9489 | 1KI 22:6 | Nígbà náà ni ọba Israẹli kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti Gileadi lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” |
9913 | 2KI 14:13 | Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi, ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà, Jehoaṣi lọ sí Jerusalẹmu, ó sì lọ wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Efraimu sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́. |
10450 | 1CH 5:18 | Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì (47,760) ènìyàn, tí ó jáde lọ sí ogún náà. |
10546 | 1CH 7:7 | Àwọn ọmọ Bela: Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (22,034) ènìyàn. |
10751 | 1CH 12:27 | àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600), |
10761 | 1CH 12:37 | Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì (40,000). |
10930 | 1CH 19:18 | Ṣùgbọ́n àwọn ará Siria sálọ kúrò níwájú Israẹli, Dafidi sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó pa Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun wọn pẹ̀lú. |
10944 | 1CH 21:5 | Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún (470,000) ọkùnrin tí ń kọ́ idà. |
10992 | 1CH 23:4 | Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. |
10993 | 1CH 23:5 | Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí. |
11115 | 1CH 27:1 | Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin. |
11116 | 1CH 27:2 | Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀. |
11118 | 1CH 27:4 | Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. |
11119 | 1CH 27:5 | Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. |
11121 | 1CH 27:7 | Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀. |
11122 | 1CH 27:8 | Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. |
11123 | 1CH 27:9 | Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. |
11124 | 1CH 27:10 | Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín rẹ̀. |
11125 | 1CH 27:11 | Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. |
11126 | 1CH 27:12 | Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. |
11127 | 1CH 27:13 | Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. |
11128 | 1CH 27:14 | Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. |
11129 | 1CH 27:15 | Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. |
11213 | 2CH 1:14 | Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu. |
11264 | 2CH 4:13 | irinwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì náà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà; |
11369 | 2CH 8:18 | Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó (450) tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá. |
11394 | 2CH 9:25 | Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu. |
11461 | 2CH 13:3 | Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára. |
11552 | 2CH 18:5 | Bẹ́ẹ̀ ọba Israẹli kó àwọn wòlíì papọ̀, irinwó (400) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Ramoti Gileadi tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?” Wọ́n dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Ọlọ́run yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” |
11732 | 2CH 25:23 | Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. |
12031 | EZR 1:10 | Ọgbọ̀n àdému wúrà 30 Irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410 Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000 |
12032 | EZR 1:11 | Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé irinwó (5,400). Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu. |