116 | GEN 5:10 | Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. |
117 | GEN 5:11 | Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú. |
123 | GEN 5:17 | Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. |
129 | GEN 5:23 | Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365). |
136 | GEN 5:30 | Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
138 | GEN 5:32 | Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti. |
234 | GEN 9:28 | Noa wà láààyè fún irinwó ọdún dín àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. |
235 | GEN 9:29 | Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín làádọ́ta (950), ó sì kú. |
278 | GEN 11:11 | Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
299 | GEN 11:32 | Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani. |
666 | GEN 25:7 | Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175). |
2406 | EXO 30:23 | “Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kilogiramu mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì, |
2407 | EXO 30:24 | kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lita mẹ́rin). |
2659 | EXO 38:25 | Fàdákà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì àti òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (1,775) ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, |
2660 | EXO 38:26 | ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ lé ẹgbẹ̀tadínlógún ó lé àádọ́jọ (603,550) ọkùnrin. |
2662 | EXO 38:28 | Ó lo òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (1,775) ṣékélì ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ọ̀já wọn. |
3626 | NUM 1:21 | Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500). |
3628 | NUM 1:23 | Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300). |
3630 | NUM 1:25 | Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650). |
3634 | NUM 1:29 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400). |
3636 | NUM 1:31 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400). |
3638 | NUM 1:33 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). |
3642 | NUM 1:37 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). |
3646 | NUM 1:41 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500). |
3648 | NUM 1:43 | Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). |
3651 | NUM 1:46 | Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta (603,550). |
3665 | NUM 2:6 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400). |
3667 | NUM 2:8 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400). |
3670 | NUM 2:11 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500). |
3672 | NUM 2:13 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje (59,300). |
3674 | NUM 2:15 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650). |
3675 | NUM 2:16 | Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́talélégbèje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì. |
3678 | NUM 2:19 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ó lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). |
3682 | NUM 2:23 | Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). |
3687 | NUM 2:28 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500). |
3689 | NUM 2:30 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé egbèje (53,400). |
3690 | NUM 2:31 | Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rin ó lé ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn. |
3691 | NUM 2:32 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta (603,550). |
3715 | NUM 3:22 | Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500). |
3743 | NUM 3:50 | Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùndínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli. |
3780 | NUM 4:36 | Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó dín làádọ́ta (2,750). |
3792 | NUM 4:48 | Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580). |
3964 | NUM 8:24 | “Èyí ni ohun tó jẹ mọ́ àwọn ọmọ Lefi, láti ọmọ ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n (25) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni kí ó máa kópa nínú iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé. |
4197 | NUM 16:2 | Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí. |
4212 | NUM 16:17 | Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta lé nígba (250) àwo tùràrí kí ẹ sì ko wá síwájú Olúwa. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.” |
4230 | NUM 16:35 | Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin tí wọ́n mú tùràrí wá. |
4501 | NUM 26:10 | Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin. Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀. |
4509 | NUM 26:18 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). |
4513 | NUM 26:22 | Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (76,500). |
4518 | NUM 26:27 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500). |
4525 | NUM 26:34 | Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700). |
4528 | NUM 26:37 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. |
4532 | NUM 26:41 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600). |
4538 | NUM 26:47 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). |
4541 | NUM 26:50 | Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbèje (45,400). |
4694 | NUM 31:28 | Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà, ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ènìyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran. |
4698 | NUM 31:32 | Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ-ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675,000) àgùntàn. |
4702 | NUM 31:36 | Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́: ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn. |
4703 | NUM 31:37 | Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn; |
4705 | NUM 31:39 | kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500), tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta (61). |
4709 | NUM 31:43 | Ààbọ̀ tí ìjọ jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn, |
4711 | NUM 31:45 | tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500). |
4718 | NUM 31:52 | Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mose àti Eleasari, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì. |
4851 | NUM 35:4 | “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ (1,500 ẹsẹ̀ bàtà) láti ògiri ìlú náà. |
6016 | JOS 8:12 | Joṣua sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọmọ-ogun pamọ́ sí àárín Beteli àti Ai, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú náà. |
6731 | JDG 8:10 | Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun. |
7091 | JDG 20:35 | Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,100) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun. |
7101 | JDG 20:45 | Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin ṣubú. |
7102 | JDG 20:46 | Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. |
7625 | 1SA 17:5 | Ó ní àṣíborí idẹ ní orí rẹ̀, ó sì wọ ẹ̀wù tí a fi idẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọ̀n ẹ̀wù náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ṣékélì idẹ. |
8704 | 2SA 24:9 | Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́. Ó sì jẹ́ ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà, àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ènìyàn. |
8879 | 1KI 5:12 | Ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005). |
9077 | 1KI 9:23 | Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà. |
9363 | 1KI 18:19 | Nísinsin yìí kó gbogbo Israẹli jọ láti pàdé mi lórí òkè Karmeli. Àti kí o sì mú àádọ́ta lé ní irinwó (450) àwọn wòlíì Baali àti irinwó (400) àwọn wòlíì òrìṣà Aṣerah tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jesebeli.” |
9366 | 1KI 18:22 | Nígbà náà ni Elijah wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́ta lé ní irinwó (450) ni wòlíì Baali. |
10100 | 2KI 19:35 | Ní alẹ́ ọjọ́ náà, angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Asiria. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà! |
10431 | 1CH 4:42 | Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. |
10453 | 1CH 5:21 | Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún (250,000), àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì (2,000), àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000). |
10628 | 1CH 9:9 | Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé. |
10758 | 1CH 12:34 | Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000). |
11176 | 1CH 29:7 | Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (10,000) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin (100,000) tálẹ́ǹtì irin. |
11233 | 2CH 2:16 | Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n (153,600). |
11361 | 2CH 8:10 | Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó lé nígba (250) àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn. |
11369 | 2CH 8:18 | Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó (450) tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá. |
11475 | 2CH 13:17 | Abijah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdààmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Israẹli. |
11750 | 2CH 26:13 | Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. |
11980 | 2CH 35:9 | Àti pẹ̀lú Konaniah àti pẹ̀lú Ṣemaiah àti Netaneli, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabiah, Jeieli àti Josabadi olórí àwọn ọmọ Lefi, ó sì pèsè ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ẹbọ ìrékọjá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Lefi. |
12032 | EZR 1:11 | Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé irinwó (5,400). Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu. |
12037 | EZR 2:5 | Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775) |
12039 | EZR 2:7 | Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin (1,254) |
12040 | EZR 2:8 | Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún (945) |
12046 | EZR 2:14 | Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (2,056) |
12047 | EZR 2:15 | Adini jẹ́ àádọ́ta lé ní irinwó ó lé mẹ́rin (454) |
12052 | EZR 2:20 | Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95). |
12054 | EZR 2:22 | Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) |