3 | GEN 1:3 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. |
6 | GEN 1:6 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” |
9 | GEN 1:9 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
11 | GEN 1:11 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
14 | GEN 1:14 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún. |
20 | GEN 1:20 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” |
88 | GEN 4:8 | Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á. |
100 | GEN 4:20 | Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. |
101 | GEN 4:21 | Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. |
121 | GEN 5:15 | Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi. |
122 | GEN 5:16 | Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
124 | GEN 5:18 | Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku. |
125 | GEN 5:19 | Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
126 | GEN 5:20 | Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú. |
138 | GEN 5:32 | Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti. |
148 | GEN 6:10 | Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti. |
173 | GEN 7:13 | Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. |
200 | GEN 8:16 | “Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. |
224 | GEN 9:18 | Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.) |
229 | GEN 9:23 | Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn. |
233 | GEN 9:27 | Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀, Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.” |
236 | GEN 10:1 | Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi. |
237 | GEN 10:2 | Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi. |
239 | GEN 10:4 | Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. |
251 | GEN 10:16 | Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, |
256 | GEN 10:21 | A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi. |
260 | GEN 10:25 | Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani. |
261 | GEN 10:26 | Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. |
264 | GEN 10:29 | Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani. |
300 | GEN 12:1 | Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́. |
328 | GEN 13:9 | Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.” |
329 | GEN 13:10 | Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) |
330 | GEN 13:11 | Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. |
361 | GEN 14:24 | Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.” |
382 | GEN 15:21 | Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.” |
457 | GEN 18:32 | Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ń kọ́?” Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, èmi kì yóò pa á run.” |
492 | GEN 19:34 | Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti baba mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú-ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.” |
562 | GEN 22:14 | Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Jehofah Jire. Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.” |
570 | GEN 22:22 | Kesedi, Haso, Pildasi, Jidlafi, àti Betueli.” |
606 | GEN 24:14 | Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘Mu ún, èmi ó sì fún àwọn ìbákasẹ rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Isaaki. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.” |
609 | GEN 24:17 | Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.” |
615 | GEN 24:23 | Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” |
635 | GEN 24:43 | Wò ó, mo dúró ní ẹ̀bá ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúńdíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ,” |
637 | GEN 24:45 | “Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rebeka jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi. Mo sì wí fun un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu.’ |
649 | GEN 24:57 | Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, “Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan an kí a sì bi í.” |
661 | GEN 25:2 | Ó sì bí Simrani, Jokṣani, Medani, Midiani, Iṣbaki, àti Ṣua |
662 | GEN 25:3 | Jokṣani ni baba Ṣeba àti Dedani, àwọn ìran Dedani ni àwọn ara Asṣuri, Letusi àti Leumiti. |
674 | GEN 25:15 | Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema. |
685 | GEN 25:26 | Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin èkejì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di Esau ni gìgísẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jakọbu. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Isaaki, nígbà tí Rebeka bí wọn. |
686 | GEN 25:27 | Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Esau sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jakọbu sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń gbé láàrín ìlú. |
687 | GEN 25:28 | Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu. |
688 | GEN 25:29 | Ní ọjọ́ kan, Jakọbu sì pa ìpẹ̀tẹ̀, Esau sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́. |
689 | GEN 25:30 | Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu.) |
690 | GEN 25:31 | Jakọbu dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.” |
692 | GEN 25:33 | Ṣùgbọ́n, Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Esau búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jakọbu. |
693 | GEN 25:34 | Nígbà náà ni Jakọbu fi àkàrà àti ìpẹ̀tẹ̀ lẹntili fún Esau. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Báyìí ni Esau gan ogún ìbí rẹ̀. |
709 | GEN 26:16 | Nígbà náà ni Abimeleki wí fún Isaaki pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.” |
721 | GEN 26:28 | Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn |
727 | GEN 26:34 | Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti. |
734 | GEN 27:6 | Rebeka sọ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń wí fún Esau ẹ̀gbọ́n rẹ pé, |
739 | GEN 27:11 | Jakọbu sì wí fún Rebeka ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Esau ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára, bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ sì ni èmi, |
742 | GEN 27:14 | Jakọbu sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rebeka sì ṣe oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Isaaki fẹ́ràn. |
743 | GEN 27:15 | Nígbà náà ni Rebeka mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Esau ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rebeka, ó sì fi wọ Jakọbu ọmọ rẹ̀ àbúrò. |
745 | GEN 27:17 | Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jakọbu ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. |
746 | GEN 27:18 | Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.” Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?” |
747 | GEN 27:19 | Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.” |
748 | GEN 27:20 | Isaaki tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?” Jakọbu sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.” |
749 | GEN 27:21 | Nígbà náà ni Isaaki wí fún Jakọbu pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni nítòótọ́ tàbí òun kọ́.” |
750 | GEN 27:22 | Jakọbu sì súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀. Isaaki sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jakọbu; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Esau.” |
751 | GEN 27:23 | Kò sì dá Jakọbu mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ ní irun bí i ti Esau arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún un |
752 | GEN 27:24 | ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?” Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.” |
753 | GEN 27:25 | Nígbà náà ni Isaaki wí pé, “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.” Jakọbu sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú. |
758 | GEN 27:30 | Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. |
764 | GEN 27:36 | Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi!” O sì béèrè pé, “Ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?” |
769 | GEN 27:41 | Esau sì kórìíra Jakọbu nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi sá à ti fẹ́rẹ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jakọbu, arákùnrin mi.” |
770 | GEN 27:42 | Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́. |
772 | GEN 27:44 | Jókòó sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀. |
774 | GEN 27:46 | Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.” |
775 | GEN 28:1 | Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani. |
779 | GEN 28:5 | Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau. |
780 | GEN 28:6 | Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani |
781 | GEN 28:7 | àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu. |
784 | GEN 28:10 | Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. |
790 | GEN 28:16 | Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” |
792 | GEN 28:18 | Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. |
794 | GEN 28:20 | Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, |
797 | GEN 29:1 | Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. |
800 | GEN 29:4 | Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” |
802 | GEN 29:6 | Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.” |
806 | GEN 29:10 | Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. |
807 | GEN 29:11 | Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. |
808 | GEN 29:12 | Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. |
809 | GEN 29:13 | Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. |
810 | GEN 29:14 | Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.” Lẹ́yìn tí Jakọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, |