45 | GEN 2:14 | Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate. |
67 | GEN 3:11 | Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?” |
102 | GEN 4:22 | Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama. |
237 | GEN 10:2 | Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi. |
238 | GEN 10:3 | Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma. |
239 | GEN 10:4 | Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. |
291 | GEN 11:24 | Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra. |
292 | GEN 11:25 | Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
293 | GEN 11:26 | Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani. |
294 | GEN 11:27 | Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti. |
295 | GEN 11:28 | Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. |
298 | GEN 11:31 | Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀. |
299 | GEN 11:32 | Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani. |
338 | GEN 14:1 | Ní àsìkò yìí ni Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu àti Tidali ọba Goyimu |
344 | GEN 14:7 | Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (ti o túmọ̀ sí Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú. |
346 | GEN 14:9 | láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). |
431 | GEN 18:6 | Abrahamu sì yára tọ Sara aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.” |
480 | GEN 19:22 | Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari). |
521 | GEN 21:7 | Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.” |
572 | GEN 22:24 | Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Reuma náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un: Teba, Gahamu, Tahasi àti Maaka. |
657 | GEN 24:65 | ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀. |
674 | GEN 25:15 | Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema. |
761 | GEN 27:33 | Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!” |
870 | GEN 30:39 | Tí àwọn ẹran bá sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára. |
882 | GEN 31:8 | Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran onítótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi onítótòtó. |
900 | GEN 31:26 | Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú. |
917 | GEN 31:43 | Labani sì dá Jakọbu lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kí ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí? |
947 | GEN 32:19 | nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” |
966 | GEN 33:5 | Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?” Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.” |
970 | GEN 33:9 | Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.” |
1052 | GEN 36:11 | Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi. |
1053 | GEN 36:12 | Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau. |
1056 | GEN 36:15 | Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, Temani, Omari, Sefi, Kenasi, |
1063 | GEN 36:22 | Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani. |
1075 | GEN 36:34 | Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. |
1081 | GEN 36:40 | Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti. |
1083 | GEN 36:42 | baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, |
1092 | GEN 37:8 | Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí. |
1126 | GEN 38:6 | Juda sì fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Tamari. |
1131 | GEN 38:11 | Nígbà náà ni Juda wí fún Tamari, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣela yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù.” Nígbà náà ni Tamari ń lọ gbé ilé baba rẹ̀. |
1132 | GEN 38:12 | Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ. |
1133 | GEN 38:13 | Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.” |
1134 | GEN 38:14 | Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya. |
1144 | GEN 38:24 | Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.” |
1149 | GEN 38:29 | Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Tamari sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Peresi. |
1272 | GEN 42:19 | Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. |
1295 | GEN 43:4 | Tí ìwọ yóò bá rán Benjamini arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ. |
1354 | GEN 44:29 | Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú orí mi lọ sí ipò òkú.’ |
1356 | GEN 44:31 | Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kùú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa tòun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́. |
1400 | GEN 46:13 | Àwọn ọmọkùnrin: Isakari! Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni. |
1569 | EXO 2:14 | Ọkùnrin náà sì dáhùn pé, “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.” |
1591 | EXO 3:11 | Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?” |
1601 | EXO 3:21 | “Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Ejibiti pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo. |
1603 | EXO 4:1 | Mose dáhùn ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?” |
1608 | EXO 4:6 | Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. |
1613 | EXO 4:11 | Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Olúwa? |
1635 | EXO 5:2 | Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.” |
1701 | EXO 7:15 | Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ. |
1844 | EXO 12:27 | Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé àwọn ọmọ Israẹli ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Ejibiti. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Ejibiti.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn. |
1932 | EXO 15:11 | Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu? |
1955 | EXO 16:7 | Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?” |
1956 | EXO 16:8 | Mose tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ́ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkùn ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.” |
2037 | EXO 19:10 | Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. |
2235 | EXO 25:39 | Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí. |
2324 | EXO 28:30 | Bákan náà ìwọ yóò sì mu Urimu àti Tumimu sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Aaroni nígbàkígbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Aaroni yóò sì máa ru ohun ti a ń fi ṣe ìpinnu fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọkàn rẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Olúwa. |
2452 | EXO 32:13 | Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ” |
2545 | EXO 35:13 | Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà. |
2718 | EXO 40:10 | Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ. |
2719 | EXO 40:11 | Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́. |
2723 | EXO 40:15 | Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.” |
2833 | LEV 5:2 | “ ‘Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi. |
2834 | LEV 5:3 | Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ohunkóhun tó lè mú ènìyàn di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi. |
2835 | LEV 5:4 | Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yówù tó ti búra láì kíyèsi ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi. |
2926 | LEV 8:8 | Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Urimu àti Tumimu sí ibi ìgbàyà náà. |
2980 | LEV 10:2 | Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa. |
3072 | LEV 13:19 | Tí ìwú funfun tàbí àmì funfun tí ó pọ́n díẹ̀ bá farahàn ní ojú ibi tí oówo náà wà: kí ẹni náà lọ sọ fún àlùfáà. |
3232 | LEV 16:30 | Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́, kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. |
3250 | LEV 17:14 | Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan, torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò. |
3326 | LEV 20:7 | “ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. |
3349 | LEV 21:3 | Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. |
3375 | LEV 22:5 | Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́. |
3403 | LEV 22:33 | Tí ó sì mú yín jáde láti Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.” |
3442 | LEV 23:39 | “ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ ṣe àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi. |
3453 | LEV 24:6 | Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa. |
3482 | LEV 25:12 | Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà. |
3503 | LEV 25:33 | Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílùú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Lefi ni ìní wọn láàrín àwọn ará Israẹli. |
3512 | LEV 25:42 | Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Israẹli jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú. |
3705 | NUM 3:12 | “Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi, |
3714 | NUM 3:21 | Ti Gerṣoni ni ìdílé Libni àti Ṣimei; àwọn ni ìdílé Gerṣoni. |
3720 | NUM 3:27 | Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati. |
3726 | NUM 3:33 | Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari. |
3738 | NUM 3:45 | “Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi. Èmi ni Olúwa. |
3766 | NUM 4:22 | “Tún ka iye àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. |
4028 | NUM 11:3 | Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tabera nítorí pé, iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrín wọn. |
4037 | NUM 11:12 | Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn. |
4047 | NUM 11:22 | Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?” |
4059 | NUM 11:34 | Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kibirotu-Hattaafa nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúwà oúnjẹ sí. |