1 | GEN 1:1 | Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. |
9 | GEN 1:9 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
11 | GEN 1:11 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
12 | GEN 1:12 | Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. |
20 | GEN 1:20 | Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” |
21 | GEN 1:21 | Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
24 | GEN 1:24 | Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
25 | GEN 1:25 | Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
26 | GEN 1:26 | Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” |
29 | GEN 1:29 | Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. |
30 | GEN 1:30 | Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà, gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
31 | GEN 1:31 | Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹfà. |
32 | GEN 2:1 | Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. |
36 | GEN 2:5 | Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. |
38 | GEN 2:7 | Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn. |
39 | GEN 2:8 | Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. |
40 | GEN 2:9 | Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. |
44 | GEN 2:13 | Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. |
51 | GEN 2:20 | Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. |
52 | GEN 2:21 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. |
53 | GEN 2:22 | Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá. |
56 | GEN 2:25 | Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n. |
57 | GEN 3:1 | Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?” |
58 | GEN 3:2 | Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwa lè jẹ lára àwọn èso igi tí ó wà nínú ọgbà, |
63 | GEN 3:7 | Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn. |
66 | GEN 3:10 | Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.” |
67 | GEN 3:11 | Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?” |
69 | GEN 3:13 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.” |
70 | GEN 3:14 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. |
74 | GEN 3:18 | Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ. |
80 | GEN 3:24 | Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni. |
87 | GEN 4:7 | Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.” |
89 | GEN 4:9 | Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?” |
90 | GEN 4:10 | Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. |
95 | GEN 4:15 | Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á. |
96 | GEN 4:16 | Kaini sì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni. |
98 | GEN 4:18 | Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki. |
99 | GEN 4:19 | Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla. |
100 | GEN 4:20 | Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. |
102 | GEN 4:22 | Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama. |
103 | GEN 4:23 | Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. |
118 | GEN 5:12 | Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli. |
119 | GEN 5:13 | Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
121 | GEN 5:15 | Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi. |
122 | GEN 5:16 | Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
123 | GEN 5:17 | Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. |
145 | GEN 6:7 | Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” |
155 | GEN 6:17 | Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. |
157 | GEN 6:19 | Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ. |
158 | GEN 6:20 | Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè. |
160 | GEN 6:22 | Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. |
164 | GEN 7:4 | Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.” |
165 | GEN 7:5 | Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pàṣẹ fún un. |
174 | GEN 7:14 | Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. |
181 | GEN 7:21 | Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. |
182 | GEN 7:22 | Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. |
183 | GEN 7:23 | Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù. |
185 | GEN 8:1 | Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. |
189 | GEN 8:5 | Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn. |
195 | GEN 8:11 | Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. |
205 | GEN 8:21 | Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. |
209 | GEN 9:3 | Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín. |
216 | GEN 9:10 | Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. |
220 | GEN 9:14 | Nígbàkígbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. |
227 | GEN 9:21 | Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. |
228 | GEN 9:22 | Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. |
229 | GEN 9:23 | Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn. |
230 | GEN 9:24 | Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. |
246 | GEN 10:11 | Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala, |
248 | GEN 10:13 | Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu. |
249 | GEN 10:14 | Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu. |
269 | GEN 11:2 | Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. |
273 | GEN 11:6 | Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. |
289 | GEN 11:22 | Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. |
290 | GEN 11:23 | Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
291 | GEN 11:24 | Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra. |
292 | GEN 11:25 | Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
293 | GEN 11:26 | Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani. |
294 | GEN 11:27 | Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti. |
296 | GEN 11:29 | Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. |
300 | GEN 12:1 | Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́. |
304 | GEN 12:5 | Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀. |
306 | GEN 12:7 | Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án. |
307 | GEN 12:8 | Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa. |
308 | GEN 12:9 | Nígbà náà ni Abramu tẹ̀síwájú sí ìhà gúúsù. |
319 | GEN 12:20 | Nígbà náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. |
320 | GEN 13:1 | Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. |
325 | GEN 13:6 | Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. |
328 | GEN 13:9 | Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.” |
333 | GEN 13:14 | Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. |
349 | GEN 14:12 | Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀. |
353 | GEN 14:16 | Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù. |
357 | GEN 14:20 | Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo. |