35 | GEN 2:4 | Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run. |
49 | GEN 2:18 | Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” |
54 | GEN 2:23 | Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” |
69 | GEN 3:13 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.” |
70 | GEN 3:14 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. |
71 | GEN 3:15 | Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.” |
72 | GEN 3:16 | Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé, “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.” |
73 | GEN 3:17 | Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. |
86 | GEN 4:6 | Nígbà náà ni Olúwa bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? |
89 | GEN 4:9 | Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?” |
107 | GEN 5:1 | Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. |
141 | GEN 6:3 | Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.” |
145 | GEN 6:7 | Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” |
151 | GEN 6:13 | Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. |
155 | GEN 6:17 | Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. |
205 | GEN 8:21 | Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. |
217 | GEN 9:11 | Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.” |
218 | GEN 9:12 | Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: |
221 | GEN 9:15 | Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. |
223 | GEN 9:17 | Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.” |
231 | GEN 9:25 | Ó wí pé, “Ègún ni fún Kenaani. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.” |
236 | GEN 10:1 | Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi. |
301 | GEN 12:2 | “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì bùkún fún ọ; èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí. |
302 | GEN 12:3 | Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.” |
306 | GEN 12:7 | Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án. |
317 | GEN 12:18 | Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Abramu, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe? |
318 | GEN 12:19 | Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí o sì máa lọ.” |
326 | GEN 13:7 | Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà. |
327 | GEN 13:8 | Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. |
329 | GEN 13:10 | Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) |
335 | GEN 13:16 | Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. |
336 | GEN 13:17 | Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.” |
361 | GEN 14:24 | Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.” |
362 | GEN 15:1 | Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé, “Abramu má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.” |
368 | GEN 15:7 | Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.” |
392 | GEN 16:10 | Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.” |
399 | GEN 17:1 | Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù. |
400 | GEN 17:2 | Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.” |
404 | GEN 17:6 | Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. |
405 | GEN 17:7 | Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. |
406 | GEN 17:8 | Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé. Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.” |
408 | GEN 17:10 | Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. |
410 | GEN 17:12 | Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. |
414 | GEN 17:16 | Èmi yóò bùkún fún un, èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípasẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.” |
435 | GEN 18:10 | Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. |
438 | GEN 18:13 | Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’ |
439 | GEN 18:14 | Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.” |
446 | GEN 18:21 | “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.” |
453 | GEN 18:28 | bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.” |
454 | GEN 18:29 | Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.” |
456 | GEN 18:31 | Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ń kọ́?” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.” |
467 | GEN 19:9 | Wọ́n sì wí fún pé, “Bì sẹ́yìn fún wa. Èyí yìí wá ṣe àtìpó láàrín wa, òun sì fẹ́ ṣe onídàájọ́! Aburú tí a ó fi ṣe ọ́ yóò pọ̀ ju tí wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọti, wọ́n sì súnmọ́ ọn láti fọ́ ìlẹ̀kùn. |
479 | GEN 19:21 | Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀. |
491 | GEN 19:33 | Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lòpọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde. |
495 | GEN 19:37 | Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Moabu. Òun ni baba ńlá àwọn ará Moabu lónìí. |
496 | GEN 19:38 | Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bene-Ami. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ammoni lónìí. |
505 | GEN 20:9 | Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.” |
509 | GEN 20:13 | Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi. Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ” |
512 | GEN 20:16 | Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún (1,000) owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.” |
527 | GEN 21:13 | Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.” |
530 | GEN 21:16 | Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. |
538 | GEN 21:24 | Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.” |
540 | GEN 21:26 | Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.” |
549 | GEN 22:1 | Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” |
555 | GEN 22:7 | Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?” |
559 | GEN 22:11 | Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” |
576 | GEN 23:4 | “Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.” |
595 | GEN 24:3 | Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé. |
611 | GEN 24:19 | Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.” |
625 | GEN 24:33 | Wọ́n sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo ní í sọ.” Labani sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.” |
640 | GEN 24:48 | Èmi sì tẹríba, mo sì wólẹ̀ fún Olúwa, mó sì fi ìbùkún fún Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, ẹni tí ó mú mi tọ ọ̀nà títọ́ láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi mú wá fún ọmọ rẹ̀. |
681 | GEN 25:22 | Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. |
684 | GEN 25:25 | Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Esau. |
689 | GEN 25:30 | Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu.) |
697 | GEN 26:4 | Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, |
703 | GEN 26:10 | Nígbà náà ni Abimeleki dáhùn pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lòpọ̀ ń kọ́? Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa.” |
717 | GEN 26:24 | Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ. Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.” |
720 | GEN 26:27 | Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?” |
729 | GEN 27:1 | Nígbà ti Isaaki di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi.” Esau sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” |
740 | GEN 27:12 | bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ń kọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.” |
746 | GEN 27:18 | Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.” Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?” |
747 | GEN 27:19 | Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.” |
752 | GEN 27:24 | ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?” Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.” |
760 | GEN 27:32 | Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.” |
773 | GEN 27:45 | Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá. Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?” |
787 | GEN 28:13 | Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. |
789 | GEN 28:15 | Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.” |
814 | GEN 29:18 | Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.” |
821 | GEN 29:25 | Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?” |
833 | GEN 30:2 | Inú sì bí Jakọbu sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?” |
885 | GEN 31:11 | Angẹli Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, ‘Jakọbu.’ Mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí.’ |
887 | GEN 31:13 | Èmi ni Ọlọ́run Beteli, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí ọ̀wọ́n, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ” |
900 | GEN 31:26 | Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú. |
901 | GEN 31:27 | Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ àti orin, pẹ̀lú ìlù àti ohun èlò orin sìn ọ́. |
913 | GEN 31:39 | Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi. |
933 | GEN 32:5 | Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí. |
941 | GEN 32:13 | Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ” |
949 | GEN 32:21 | Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. |
955 | GEN 32:27 | Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.” |