2 | GEN 1:2 | Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. |
22 | GEN 1:22 | Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” |
26 | GEN 1:26 | Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” |
28 | GEN 1:28 | Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.” |
57 | GEN 3:1 | Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?” |
59 | GEN 3:3 | ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ” |
60 | GEN 3:4 | Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.” |
90 | GEN 4:10 | Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. |
93 | GEN 4:13 | Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ. |
207 | GEN 9:1 | Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. |
208 | GEN 9:2 | Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. |
212 | GEN 9:6 | “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn. |
270 | GEN 11:3 | Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). |
271 | GEN 11:4 | Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ, kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” |
274 | GEN 11:7 | Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.” |
350 | GEN 14:13 | Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Abramu, ará Heberu ni. Abramu sá ti tẹ̀dó sí ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre ará Amori, arákùnrin Eṣkolu àti Aneri: àwọn ẹni tí ó ń bá Abramu ní àṣepọ̀. |
356 | GEN 14:19 | Ó sì súre fún Abramu, wí pé, “Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. |
409 | GEN 17:11 | Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. |
429 | GEN 18:4 | Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín. |
430 | GEN 18:5 | Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀síwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín.” Wọn sì wí pé “Ó dára.” |
440 | GEN 18:15 | Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.” |
460 | GEN 19:2 | Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.” Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.” |
472 | GEN 19:14 | Nígbà náà ni Lọti jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí, nítorí Olúwa fẹ́ pa ìlú yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe. |
478 | GEN 19:20 | Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòsí láti sá sí: jẹ́ kí n sálọ síbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́? Ẹ̀mí mi yóò sì yè.” |
505 | GEN 20:9 | Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.” |
519 | GEN 21:5 | Ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki. |
553 | GEN 22:5 | Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.” |
646 | GEN 24:54 | Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.” |
648 | GEN 24:56 | Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá mi dúró, Olúwa sá à ti ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ.” |
704 | GEN 26:11 | Nígbà náà ni Abimeleki pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú.” |
791 | GEN 28:17 | Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.” |
800 | GEN 29:4 | Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” |
803 | GEN 29:7 | Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.” |
810 | GEN 29:14 | Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.” Lẹ́yìn tí Jakọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, |
880 | GEN 31:6 | Ẹ sá à mọ̀ pé, mo ti fi gbogbo agbára mi ṣiṣẹ́ fún baba yín, |
905 | GEN 31:31 | Jakọbu dá Labani lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipátipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi. |
910 | GEN 31:36 | Inú sì bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjà pé, “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn? |
913 | GEN 31:39 | Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi. |
920 | GEN 31:46 | Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkìtì wọ́n sì jẹun níbẹ̀. |
945 | GEN 32:17 | Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.” |
947 | GEN 32:19 | nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” |
990 | GEN 34:9 | Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrín ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa. |
991 | GEN 34:10 | Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.” |
992 | GEN 34:11 | Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà. |
1011 | GEN 34:30 | Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.” |
1014 | GEN 35:2 | Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. |
1040 | GEN 35:28 | Ẹni ọgọ́sàn-án ọdún ni Isaaki. |
1090 | GEN 37:6 | O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá, |
1101 | GEN 37:17 | Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani. |
1104 | GEN 37:20 | “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.” |
1105 | GEN 37:21 | Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, |
1107 | GEN 37:23 | Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— |
1111 | GEN 37:27 | Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ. |
1138 | GEN 38:18 | Juda sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípasẹ̀ rẹ̀. |
1144 | GEN 38:24 | Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.” |
1164 | GEN 39:14 | ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. |
1167 | GEN 39:17 | Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. |
1181 | GEN 40:8 | Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.” |
1185 | GEN 40:12 | Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. |
1239 | GEN 41:43 | Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. |
1251 | GEN 41:55 | Nígbà tí àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Farao. Nígbà náà ni Farao wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Josẹfu, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.” |
1255 | GEN 42:2 | “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.” |
1265 | GEN 42:12 | Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.” |
1269 | GEN 42:16 | Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” |
1281 | GEN 42:28 | Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.” Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.” |
1288 | GEN 42:35 | Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. |
1289 | GEN 42:36 | Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ. Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí!” |
1293 | GEN 43:2 | Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Ejibiti tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ si wá fún wa.” |
1294 | GEN 43:3 | Ṣùgbọ́n Juda wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’. |
1296 | GEN 43:5 | Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ” |
1298 | GEN 43:7 | Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?” |
1304 | GEN 43:13 | Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ. |
1309 | GEN 43:18 | Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” |
1335 | GEN 44:10 | Ó wí pé, “Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ. Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi. Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láìlẹ́bi.” |
1342 | GEN 44:17 | Ṣùgbọ́n Josẹfu dáhùn pé, “Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.” |
1345 | GEN 44:20 | Àwa sì wí fún olúwa mi pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn án rẹ̀.’ |
1346 | GEN 44:21 | “Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’ |
1348 | GEN 44:23 | Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’ |
1350 | GEN 44:25 | “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’ |
1352 | GEN 44:27 | “Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi. |
1363 | GEN 45:4 | Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti! |
1371 | GEN 45:12 | “Ẹ̀yin fúnra yín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀. |
1372 | GEN 45:13 | Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.” |
1378 | GEN 45:19 | “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí. ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá. |
1379 | GEN 45:20 | Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Ejibiti yóò jẹ́ tiyín.’ ” |
1383 | GEN 45:24 | Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!” |
1385 | GEN 45:26 | Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́. |
1399 | GEN 46:12 | Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. |
1437 | GEN 47:16 | Josẹfu wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.” |
1445 | GEN 47:24 | Ṣùgbọ́n nígbà tí ìre oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdákan nínú ìdámárùn-ún rẹ̀ fún Farao. Ẹ le pa ìdámẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.” |
1475 | GEN 49:1 | Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín. |
1476 | GEN 49:2 | “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu; ẹ fetí sí Israẹli baba yín. |
1478 | GEN 49:4 | Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀). |
1493 | GEN 49:19 | “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi, ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn. |
1525 | GEN 50:18 | Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, “Ẹrú rẹ ni a jẹ́.” |
1526 | GEN 50:19 | Ṣùgbọ́n Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí? |
1542 | EXO 1:9 | Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. |
1543 | EXO 1:10 | Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.” |
1575 | EXO 2:20 | Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.” |