Wildebeest analysis examples for:   yor-yor   Word-Word,    February 25, 2023 at 01:36    Script wb_pprint_html.py   by Ulf Hermjakob

39  GEN 2:8  Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.
102  GEN 4:22  Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama.
269  GEN 11:2  Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.
307  GEN 12:8  Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.
342  GEN 14:5  Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu,
356  GEN 14:19  Ó sì súre fún Abramu, wí pé, “Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
359  GEN 14:22  Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
414  GEN 17:16  Èmi yóò bùkún fún un, èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípasẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.”
415  GEN 17:17  Abrahamu sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún? Sara tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí?”
473  GEN 19:15  Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
507  GEN 20:11  Abrahamu sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi.
602  GEN 24:10  Ìránṣẹ́ náà sì mú ìbákasẹ mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Naharaimu, sí ìlú Nahori,
776  GEN 28:2  Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ.
779  GEN 28:5  Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau.
788  GEN 28:14  Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.
892  GEN 31:18  Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kójọ ni Padani-Aramu, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kenaani.
921  GEN 31:47  Labani sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jegari-Sahaduta, ṣùgbọ́n Jakọbu pè é ni Galeedi.
1019  GEN 35:7  Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli, nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.
1021  GEN 35:9  Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un.
1030  GEN 35:18  Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi, torí pé ó ń kú lọ, ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni, ọmọ ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini, ọmọ oókan àyà mi.
1033  GEN 35:21  Israẹli sì ń bá ìrìnàjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Ederi, ilé ìṣọ́ Ederi.
1471  GEN 48:19  Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.”
1899  EXO 14:9  Àwọn ará Ejibiti ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹṣin kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bàá òkun ní ìhà Pi-Hahirotu, ni òdìkejì Baali-Ṣefoni.
1966  EXO 16:18  Nígbà tí wọ́n fi òsùwọ̀n omeri wọ̀n-ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un.
2021  EXO 18:21  Ṣa àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ; yàn wọ́n ṣe olórí, lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá.
2285  EXO 27:12  “Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.
2286  EXO 27:13  Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.
2287  EXO 27:14  Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
2503  EXO 34:6  Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́,
2635  EXO 38:1  Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé.
2647  EXO 38:13  Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀.
2652  EXO 38:18  Aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni gígùn rẹ̀, àti gíga rẹ̀ ní ìbò rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó bá aṣọ títa àgbàlá wọ̀n-ọn-nì ṣe déédé,
3558  LEV 26:33  Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun.
3577  LEV 27:6  Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin.
3662  NUM 2:3  ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
3868  NUM 7:17  akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
3874  NUM 7:23  Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.
3880  NUM 7:29  Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni.
3886  NUM 7:35  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
3892  NUM 7:41  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
3898  NUM 7:47  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliasafu ọmọ Deueli.
3904  NUM 7:53  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliṣama ọmọ Ammihudu.
3910  NUM 7:59  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Gamalieli ọmọ Pedasuri.
3916  NUM 7:65  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Abidani ọmọ Gideoni.
3922  NUM 7:71  àti fún ẹbọ ti ẹbọ àlàáfíà, akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn márùn-ún ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ tí Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
3928  NUM 7:77  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Pagieli ọmọ Okanri.
3934  NUM 7:83  màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani.
4044  NUM 11:19  Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán,
4121  NUM 14:12  Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”
4352  NUM 21:11  Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn.
4463  NUM 24:16  ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí, tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí:
4467  NUM 24:20  Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”
4592  NUM 28:13  pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná.
4636  NUM 29:26  “ ‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.
4637  NUM 29:27  Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà.
4640  NUM 29:30  Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
4643  NUM 29:33  Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
4647  NUM 29:37  Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
4674  NUM 31:8  Wọ́n sì pa àwọn ọba Midiani pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Efi, Rekemu, Suri àti Huri, àti Reba: ọba Midiani márùn-ún, wọ́n sì fi idà pa Balaamu ọmọ Beori.
4680  NUM 31:14  Inú bí Mose sí àwọn olórí ọmọ-ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún tí wọ́n ti ogun dé.
4716  NUM 31:50  Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka-àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”
4756  NUM 32:36  pẹ̀lú Beti-Nimra, àti Beti-Harani ìlú olódi, àti agbo fún àgùntàn.
4769  NUM 33:7  Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli.
4770  NUM 33:8  Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín òkun kọjá lọ sí aginjù. Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara.
4800  NUM 33:38  Nípa àṣẹ Olúwa, Aaroni àlùfáà gùn orí òkè Hori, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá.
4806  NUM 33:44  Wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Abarimu, ní agbègbè Moabu.
4821  NUM 34:3  “ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,
4822  NUM 34:4  kọjá lọ sí gúúsù Akrabbimu, tẹ̀síwájú lọ si Sini, kó bọ́ si gúúsù Kadeṣi-Barnea, kí o sì dé Hasari-Addari, kí o sì kọjá sí Asmoni.
4827  NUM 34:9  tẹ̀síwájú lọ sí Sifroni, kí o sì fò pín si ní Hasari-Enani, èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.
4831  NUM 34:13  Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀.
4833  NUM 34:15  Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.”
4852  NUM 35:5  Lẹ́yìn ìlú náà, wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà àríwá, kí ìlú náà sì wà ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.
4896  DEU 1:2  (Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.)
4948  DEU 2:8  Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Esau tí ń gbé ní Seiri. A yà kúrò ní ọ̀nà Arabah èyí tí ó wá láti Elati àti Esioni-Geberi, a sì rìn gba ọ̀nà aginjù Moabu.
5004  DEU 3:27  Gòkè lọ sí orí òkè Pisga, sì wò yíká ìwọ̀-oòrùn, ìlà-oòrùn, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jordani yìí.
5182  DEU 9:23  Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.
5240  DEU 11:30  Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jordani ní apá ìwọ̀-oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó More, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbègbè Gilgali.
5327  DEU 15:6  Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí.
5374  DEU 17:8  Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn.
5677  DEU 28:64  Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.
5704  DEU 29:22  Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-oòrùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè so èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Sodomu àti Gomorra, Adma àti Seboimu, tí Olúwa bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀, àti ìkáàánú rẹ̀.
5711  DEU 30:1  Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
5803  DEU 32:43  Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀; yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀ yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.
5829  DEU 33:17  Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù; ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni. Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè, pàápàá títí dé òpin ayé. Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu, àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.”
5847  DEU 34:6  Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà.
6076  JOS 10:10  Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.
6092  JOS 10:26  Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.
6117  JOS 11:8  Olúwa sì fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sidoni ńlá, sí Misrefoti-Maimu, àti sí àfonífojì Mispa ní ìlà-oòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.
6125  JOS 11:16  Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo gúúsù, gbogbo agbègbè Goṣeni, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Israẹli,
6135  JOS 12:3  Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.
6152  JOS 12:20  ọba Ṣimroni-Meroni, ọ̀kan ọba Akṣafu, ọ̀kan
6161  JOS 13:5  àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali; àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni dé Lebo-Hamati.
6162  JOS 13:6  “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,
6176  JOS 13:20  Beti-Peori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga, àti Beti-Jeṣimoti
6183  JOS 13:27  àti ní àfonífojì Beti-Haramu, Beti-Nimra, Sukkoti àti Safoni pẹ̀lú ìyókù agbègbè ilẹ̀ Sihoni ọba Heṣboni (ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani, agbègbè rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kinnereti).
6210  JOS 15:6  ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni.
6211  JOS 15:7  Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli.
6214  JOS 15:10  Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna.
6220  JOS 15:16  Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.”
6231  JOS 15:27  Hasari Gada, Heṣmoni, Beti-Peleti,