390 | GEN 16:8 | Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?” Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.” |
465 | GEN 19:7 | Ó sì wí pé, “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe ṣe ohun búburú yìí, |
476 | GEN 19:18 | Ṣùgbọ́n Lọti wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́! |
499 | GEN 20:3 | Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ n nì, aya ẹni kan ní íṣe.” |
531 | GEN 21:17 | Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí. |
553 | GEN 22:5 | Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.” |
583 | GEN 23:11 | pé, “Rárá, olúwa mi. Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.” |
599 | GEN 24:7 | “Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. |
604 | GEN 24:12 | Ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Abrahamu olúwa mi. |
610 | GEN 24:18 | Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un mu. |
623 | GEN 24:31 | Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ìbákasẹ rẹ.” |
702 | GEN 26:9 | Nígbà náà ni Abimeleki ránṣẹ́ pe Isaaki ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí ìwọ fi wí fún wa pé arábìnrin mi ni?” Isaaki sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.” |
803 | GEN 29:7 | Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.” |
898 | GEN 31:24 | Ọlọ́run sì yọ sí Labani ará Aramu lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.” |
976 | GEN 33:15 | Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?” |
1119 | GEN 37:35 | Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí isà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Josẹfu sì sọkún fún un. |
1158 | GEN 39:8 | Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. |
1470 | GEN 48:18 | Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.” |
1477 | GEN 49:3 | “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi, títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára. |
1482 | GEN 49:8 | “Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ, ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ. |
1596 | EXO 3:16 | “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. |
1655 | EXO 5:22 | Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi? |
1667 | EXO 6:11 | “Lọ, sọ fún Farao ọba Ejibiti pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” |
2048 | EXO 19:21 | Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé. |
2199 | EXO 25:3 | “Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ wọn: “wúrà, fàdákà àti idẹ; |
2440 | EXO 32:1 | Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.” |
2443 | EXO 32:4 | Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.” |
2450 | EXO 32:11 | Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára? |
2470 | EXO 32:31 | Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. |
2503 | EXO 34:6 | Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, |
2506 | EXO 34:9 | Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.” |
2537 | EXO 35:5 | Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; |
4019 | NUM 10:30 | Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.” |
4024 | NUM 10:35 | Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé, “Dìde, Olúwa! Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká, kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.” |
4025 | NUM 10:36 | Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé, “Padà, Olúwa, sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.” |
4073 | NUM 12:13 | Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!” |
4126 | NUM 14:17 | “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé, |
4217 | NUM 16:22 | Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?” |
4259 | NUM 18:1 | Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín. |
4414 | NUM 22:38 | Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Kíyèsi, èmi tọ̀ ọ́ wá, èmi kò ha ní agbára kan nísinsin yìí rárá láti wí ohun kan? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Ọlọ́run fi sí mi lẹ́nu.” |
4435 | NUM 23:18 | Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ, “Dìde, Balaki; kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori. |
4470 | NUM 24:23 | Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí? |
4723 | NUM 32:3 | “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni. |
5012 | DEU 4:6 | Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.” |
5432 | DEU 20:3 | yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. |
5901 | JOS 3:6 | Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn. |
5985 | JOS 7:7 | Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani? |
5991 | JOS 7:13 | “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò. |
6589 | JDG 3:19 | Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnra rẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. |
6607 | JDG 4:6 | Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé, ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori. |
6669 | JDG 6:13 | Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” |
6705 | JDG 7:9 | Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́. |
6793 | JDG 9:37 | Gaali ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan sì ń ti ọ̀nà igi óákù Meonenimu wá.” |
6995 | JDG 17:13 | Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.” |
7139 | RUT 1:10 | Wọ́n sì wí fún un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.” |
7192 | RUT 3:18 | Naomi sì wí fún un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí, nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.” |
7294 | 1SA 3:16 | Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.” Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.” |
7398 | 1SA 9:5 | Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.” |
7402 | 1SA 9:9 | (Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì). |
7419 | 1SA 9:26 | Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, ó pe Saulu sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Saulu múra tán òun àti Samuẹli jọ jáde lọ síta. |
7511 | 1SA 14:1 | Ní ọjọ́ kan, Jonatani ọmọ Saulu wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Filistini tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀. |
7516 | 1SA 14:6 | Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.” |
7675 | 1SA 17:55 | Bí Saulu sì ti wo Dafidi bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Filistini, ó wí fún Abneri, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Abneri, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Abneri dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.” |
7678 | 1SA 17:58 | Saulu béèrè pé, “Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́?” Dafidi dáhùn pé, “Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jese ti Bẹtilẹhẹmu.” |
7743 | 1SA 20:11 | Jonatani wí fún Dafidi pé, “Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá.” Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ. |
7768 | 1SA 20:36 | Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀. |
7772 | 1SA 20:40 | Jonatani sì fi apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú.” |
7806 | 1SA 22:16 | Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.” |
7817 | 1SA 23:4 | Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.” |
7989 | 1SA 30:8 | Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa, nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.” |
8040 | 2SA 1:15 | Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú. |
8186 | 2SA 7:3 | Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” |
8188 | 2SA 7:5 | “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. |
8191 | 2SA 7:8 | “Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli. |
8208 | 2SA 7:25 | “Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí. |
8326 | 2SA 13:6 | Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn, ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.” |
8335 | 2SA 13:15 | Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!” |
8337 | 2SA 13:17 | Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” |
8363 | 2SA 14:4 | Nígbà tí obìnrin àrá Tekoa sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, “Ọba, gbà mi.” |
8423 | 2SA 15:31 | Ẹnìkan sì sọ fún Dafidi pé, “Ahitofeli wà nínú àwọn aṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú Absalomu.” Dafidi sì wí pé, “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Ahitofeli di asán.” |
8436 | 2SA 16:7 | Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. |
8502 | 2SA 18:21 | Joabu sì wí fún Kuṣi pé, “Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Kuṣi sì wólẹ̀ fún Joabu ó sì sáré. |
8503 | 2SA 18:22 | Ahimasi ọmọ Sadoku sì tún wí fún Joabu pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tọ Kuṣi lẹ́yìn.” Joabu sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìròyìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.” |
8713 | 2SA 24:18 | Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” |
8793 | 1KI 2:20 | Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; èmi kì yóò kọ̀ ọ́.” |
8802 | 1KI 2:29 | A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.” |
8845 | 1KI 3:26 | Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!” |
9223 | 1KI 14:2 | Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. |
9345 | 1KI 18:1 | Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá pé, “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Ahabu, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.” |
9380 | 1KI 18:36 | Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ. |
9383 | 1KI 18:39 | Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “Olúwa, òun ni Ọlọ́run! Olúwa, òun ni Ọlọ́run!” |
9385 | 1KI 18:41 | Elijah sì wí fún Ahabu pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.” |
9387 | 1KI 18:43 | Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà Òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.” Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.” Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.” |
9388 | 1KI 18:44 | Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọsánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú Òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.” Elijah sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Ahabu pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ” |
9395 | 1KI 19:5 | Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ. Sì wò ó, angẹli fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí o jẹun.” |
9397 | 1KI 19:7 | Angẹli Olúwa sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” |
9433 | 1KI 20:22 | Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Israẹli, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Aramu yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.” |
9489 | 1KI 22:6 | Nígbà náà ni ọba Israẹli kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti Gileadi lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” |
9498 | 1KI 22:15 | Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaiah, ṣé kí a lọ bá Ramoti Gileadi jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀?” Ó sì dáhùn wí pé, “Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” |
9593 | 2KI 3:13 | Eliṣa wí fún ọba Israẹli pé, “Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa? Lọ sọ́dọ̀ wòlíì baba rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ.” Ọba Israẹli dá a lóhùn, “Rárá, nítorí Olúwa ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Moabu lọ́wọ́.” |