Wildebeest analysis examples for:   yor-yor   (Number).    February 25, 2023 at 01:36    Script wb_pprint_html.py   by Ulf Hermjakob

129  GEN 5:23  Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365).
573  GEN 23:1  Sara sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádóje (127).
666  GEN 25:7  Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175).
1449  GEN 47:28  Jakọbu gbé ní Ejibiti fún ọdún mẹ́tàdínlógún iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹ́tàdínlàádọ́jọ (147).
1857  EXO 12:40  Iye ọdún ti àwọn ará Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ejibiti jẹ́ irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430).
4705  NUM 31:39  kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500), tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta (61).
4706  NUM 31:40  Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n (32).
7502  1SA 13:15  Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600).
9426  1KI 20:15  Nígbà náà ni Ahabu ka àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232). Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tókù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000).
10625  1CH 9:6  Ní ti ará Sera: Jeueli. Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
10628  1CH 9:9  Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
10641  1CH 9:22  Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn.
11058  1CH 25:7  Àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún Olúwa, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́jọ (288).
12052  EZR 2:20  Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95).
12064  EZR 2:32  Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó (320).
12072  EZR 2:40  Àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ọmọ Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74).
12073  EZR 2:41  Àwọn akọrin. Àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádóje (128).
12074  EZR 2:42  Àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàndínlógóje (139).
12090  EZR 2:58  Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).
12092  EZR 2:60  Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (652).
12450  NEH 7:25  Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95).
12461  NEH 7:36  Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345).
12468  NEH 7:43  Àwọn ọmọ Lefi: àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74).
12469  NEH 7:44  Àwọn akọrin: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ (148).
12470  NEH 7:45  Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje (138).
12485  NEH 7:60  Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).
12487  NEH 7:62  Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642).
12492  NEH 7:67  yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245).
12606  NEH 11:14  àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin jẹ́ méjìdínláàádóje (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sabdieli ọmọ Hagedolimu.
12610  NEH 11:18  Àwọn ọmọ Lefi nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284).
20375  JER 52:30  Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín márùn-ún (745). Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún (4,600).
20603  EZK 4:5  Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).
20607  EZK 4:9  “Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).
27960  ACT 27:37  Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó dín mẹ́rin (276).
30942  REV 11:2  Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42).
30995  REV 13:18  Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà, nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666).