7841 | 1SA 23:28 | Saulu sì padà kúrò ní lílépa Dafidi, ó sì lọ pàdé àwọn Filistini nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Selahamalekoti (èyí tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìpinyà”). |
23236 | MAT 1:23 | “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”). |
24231 | MAT 27:33 | Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta (èyí tí í ṣe “Ibi Agbárí”). |
24374 | MRK 3:17 | Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí “àwọn ọmọ àrá”). |