65 | GEN 3:9 | Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?” |
67 | GEN 3:11 | Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?” |
69 | GEN 3:13 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.” |
89 | GEN 4:9 | Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?” |
369 | GEN 15:8 | Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?” |
390 | GEN 16:8 | Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?” Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.” |
415 | GEN 17:17 | Abrahamu sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún? Sara tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí?” |
434 | GEN 18:9 | Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ń kọ́?” Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.” |
437 | GEN 18:12 | Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?” |
448 | GEN 18:23 | Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” |
450 | GEN 18:25 | Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?” |
453 | GEN 18:28 | bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.” |
454 | GEN 18:29 | Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.” |
455 | GEN 18:30 | Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀ ń kọ́?” Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, èmi kì yóò pa ìlú run.” |
456 | GEN 18:31 | Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ń kọ́?” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.” |
457 | GEN 18:32 | Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ń kọ́?” Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, èmi kì yóò pa á run.” |
506 | GEN 20:10 | Abimeleki sì bi Abrahamu pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?” |
555 | GEN 22:7 | Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?” |
597 | GEN 24:5 | Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?” |
615 | GEN 24:23 | Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” |
657 | GEN 24:65 | ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀. |
691 | GEN 25:32 | Esau sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?” |
702 | GEN 26:9 | Nígbà náà ni Abimeleki ránṣẹ́ pe Isaaki ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí ìwọ fi wí fún wa pé arábìnrin mi ni?” Isaaki sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.” |
720 | GEN 26:27 | Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?” |
746 | GEN 27:18 | Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.” Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?” |
748 | GEN 27:20 | Isaaki tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?” Jakọbu sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.” |
752 | GEN 27:24 | ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?” Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.” |
760 | GEN 27:32 | Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.” |
764 | GEN 27:36 | Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi!” O sì béèrè pé, “Ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?” |
765 | GEN 27:37 | Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?” |
773 | GEN 27:45 | Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá. Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?” |
800 | GEN 29:4 | Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” |
801 | GEN 29:5 | Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.” |
802 | GEN 29:6 | Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.” |
821 | GEN 29:25 | Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?” |
833 | GEN 30:2 | Inú sì bí Jakọbu sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?” |
846 | GEN 30:15 | Ṣùgbọ́n Lea dalóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba èso mándrákì ọmọ mi pẹ̀lú?” Rakeli sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí èso mándrákì ọmọ rẹ.” |
862 | GEN 30:31 | Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn. |
904 | GEN 31:30 | Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?” |
958 | GEN 32:30 | Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀. |
966 | GEN 33:5 | Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?” Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.” |
969 | GEN 33:8 | Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?” Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” |
976 | GEN 33:15 | Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?” |
1012 | GEN 34:31 | Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?” |
1092 | GEN 37:8 | Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí. |
1094 | GEN 37:10 | Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “Irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?” |
1099 | GEN 37:15 | ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?” |
1100 | GEN 37:16 | Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?” |
1114 | GEN 37:30 | Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdékùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?” |
1137 | GEN 38:17 | Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ sí ọ láti inú agbo ẹran.” Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?” |
1138 | GEN 38:18 | Juda sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípasẹ̀ rẹ̀. |
1141 | GEN 38:21 | Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni alágbèrè ojúbọ òrìṣà tí ó wà ní etí ọ̀nà Enaimu wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbí.” |
1149 | GEN 38:29 | Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Tamari sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Peresi. |
1159 | GEN 39:9 | Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” |
1180 | GEN 40:7 | Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?” |
1234 | GEN 41:38 | Farao sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?” |
1254 | GEN 42:1 | Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” |
1260 | GEN 42:7 | Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.” |
1297 | GEN 43:6 | Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?” |
1318 | GEN 43:27 | Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?” |
1320 | GEN 43:29 | Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi.” |
1340 | GEN 44:15 | Josẹfu wí fún wọn pé, “Èwo ni èyí tí ẹ ṣe yìí? Ṣe ẹ kò mọ pé, ènìyàn bí èmi le è rí ìdí nǹkan nípa ṣíṣe àyẹ̀wò?” |
1362 | GEN 45:3 | Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀. |
1424 | GEN 47:3 | Farao béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kí ni iṣẹ́ yín?” Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran.” |
1429 | GEN 47:8 | Farao béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?” |
1460 | GEN 48:8 | Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?” |
1522 | GEN 50:15 | Nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Josẹfu ṣì fi wá sínú ń kọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀san gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?” |
1551 | EXO 1:18 | Ọba Ejibiti pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?” |
1562 | EXO 2:7 | Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé, “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?” |
1568 | EXO 2:13 | Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?” |
1569 | EXO 2:14 | Ọkùnrin náà sì dáhùn pé, “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.” |
1573 | EXO 2:18 | Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Reueli baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?” |
1591 | EXO 3:11 | Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?” |
1593 | EXO 3:13 | Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?” |
1604 | EXO 4:2 | Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?” Ó sì dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.” |
1647 | EXO 5:14 | Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?” |
1668 | EXO 6:12 | Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Israẹli tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Farao yóò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?” |
1686 | EXO 6:30 | Ṣùgbọ́n Mose sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ́n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Farao yóò ṣe fi etí sí mi?” |
1785 | EXO 10:7 | Àwọn ìjòyè Farao sọ fún un, “Yóò ti pẹ́ to tí ọkùnrin yìí yóò máa jẹ́ ìkẹ́kùn fún wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí síbẹ̀ pé, ilẹ̀ Ejibiti ti parun tán?” |
1945 | EXO 15:24 | Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?” |
1955 | EXO 16:7 | Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?” |
1963 | EXO 16:15 | Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i ṣe. Mose sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ. |
1986 | EXO 17:2 | Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mose, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.” Mose dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?” |
1991 | EXO 17:7 | Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Massa àti Meriba, nítorí àwọn ọmọ Israẹli sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?” |
2014 | EXO 18:14 | Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?” |
2460 | EXO 32:21 | Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?” |
2490 | EXO 33:16 | Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?” |
2997 | LEV 10:19 | Aaroni sì dá Mose lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún ṣẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?” |
3490 | LEV 25:20 | Ẹ le béèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?” |
4045 | NUM 11:20 | ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan, títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ” |
4047 | NUM 11:22 | Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?” |
4062 | NUM 12:2 | Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí. |
4068 | NUM 12:8 | Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán Olúwa. Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?” |
4112 | NUM 14:3 | Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?” |
4198 | NUM 16:3 | Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mose àti Aaroni, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrín wọn, Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn Olúwa lọ?” |
4206 | NUM 16:11 | Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?” |
4217 | NUM 16:22 | Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?” |
4258 | NUM 17:28 | Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabanaku Olúwa yóò kú. Ṣé gbogbo wa ni yóò kú?” |
4322 | NUM 20:10 | Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” |
4385 | NUM 22:9 | Ọlọ́run tọ Balaamu wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?” |