57 | GEN 3:1 | Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?” |
1298 | GEN 43:7 | Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?” |
1603 | EXO 4:1 | Mose dáhùn ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?” |
7786 | 1SA 21:12 | Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?” |
9163 | 1KI 12:9 | Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀’?” |
9635 | 2KI 4:28 | “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pé kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?” |
23911 | MAT 21:16 | Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?” Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé, “ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú, ni a ó ti máa yìn mí’?” |
24753 | MRK 12:11 | Èyí ni iṣẹ́ Olúwa ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?” |
26368 | JHN 6:42 | Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?” |
26433 | JHN 7:36 | Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ‘Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi,’ àti ‘Ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà’?” |
26472 | JHN 8:22 | Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?” |
26483 | JHN 8:33 | Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?” |
26683 | JHN 12:34 | Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé, ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé Ọmọ Ènìyàn sókè’? Ta ni ó ń jẹ́ ‘Ọmọ Ènìyàn yìí’?” |
26812 | JHN 16:17 | Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, ‘Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi, àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba’?” |