509 | GEN 20:13 | Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi. Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ” |
3850 | NUM 6:26 | Kí Olúwa bojú wò yín, kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’ |
4045 | NUM 11:20 | ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan, títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ” |
6050 | JOS 9:11 | Àwọn àgbàgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’ |
6456 | JOS 22:28 | “Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé, “Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.” ’ |
7278 | 1SA 2:36 | Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ” |
7422 | 1SA 10:2 | Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Selsa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’ |
8190 | 2SA 7:7 | Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’ |
8391 | 2SA 14:32 | Absalomu sì dá Joabu lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Geṣuri wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn ún síbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.” |
9178 | 1KI 12:24 | ‘Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Israẹli. Kì olúkúlùkù yín padà sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.” ’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. |
9543 | 2KI 1:6 | Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àní àní ìwọ yóò kùú!” ’ ” |
9763 | 2KI 9:3 | Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ Nígbà náà, ṣí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré, má ṣe jáfara!” |
9772 | 2KI 9:12 | “Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Sọ fún wa.” Jehu wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ ” |
9797 | 2KI 9:37 | Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, “Jesebeli ni èyí.” ’ ” |
10874 | 1CH 17:6 | Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’ |
18631 | ISA 44:28 | ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ” |
19676 | JER 27:11 | Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ” |
20793 | EZK 13:16 | Àwọn wòlíì Israẹli tí ń sọtẹ́lẹ̀ sí Jerusalẹmu, tí wọn ríran àlàáfíà sí i nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí.” ’ |
21169 | EZK 25:17 | Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.” ’ ” |
21359 | EZK 33:10 | “Ọmọ ènìyàn; sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí yìí ní ìwọ sọ: “Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń ṣòfò dànù nítorí wọn. Bá wó wa ni a ṣe lè yè?” ’ |
21430 | EZK 36:2 | Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Háà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’ |
21507 | EZK 38:13 | Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’ ” |
23985 | MAT 22:44 | “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’ |
24778 | MRK 12:36 | Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’ |
25891 | LUK 20:43 | títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’ |
26034 | LUK 23:30 | Nígbà náà ni “ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Yí lù wá!” Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’ |
27053 | ACT 2:35 | títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ dí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’ |