111 | GEN 5:5 | Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú. |
122 | GEN 5:16 | Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
128 | GEN 5:22 | Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
129 | GEN 5:23 | Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365). |
153 | GEN 6:15 | Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. |
234 | GEN 9:28 | Noa wà láààyè fún irinwó ọdún dín àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. |
280 | GEN 11:13 | Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. |
282 | GEN 11:15 | Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
284 | GEN 11:17 | Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. |
351 | GEN 14:14 | Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó lé lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì (318) ènìyàn, ó sì lépa wọn títí dé Dani. |
676 | GEN 25:17 | Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. |
1381 | GEN 45:22 | Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún. |
1402 | GEN 46:15 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀. |
1672 | EXO 6:16 | Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Lefi lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé. |
1674 | EXO 6:18 | Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé. |
1676 | EXO 6:20 | Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un. Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé. |
1857 | EXO 12:40 | Iye ọdún ti àwọn ará Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ejibiti jẹ́ irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430). |
1858 | EXO 12:41 | Ó sì ní òpin irinwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430), ní ọjọ́ náà gan an, ni ó sì ṣe tí gbogbo ogun Olúwa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. |
2467 | EXO 32:28 | Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ènìyàn. |
2658 | EXO 38:24 | Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti òjìlélẹ́ẹ̀gbẹ́rín ó dín mẹ́wàá (730) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́. |
2660 | EXO 38:26 | ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ lé ẹgbẹ̀tadínlógún ó lé àádọ́jọ (603,550) ọkùnrin. |
3628 | NUM 1:23 | Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300). |
3640 | NUM 1:35 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹẹ́rìndínlógún ó lé igba (32,200). |
3642 | NUM 1:37 | Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). |
3648 | NUM 1:43 | Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). |
3651 | NUM 1:46 | Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta (603,550). |
3672 | NUM 2:13 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje (59,300). |
3680 | NUM 2:21 | Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba (32,200). |
3682 | NUM 2:23 | Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). |
3689 | NUM 2:30 | Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé egbèje (53,400). |
3691 | NUM 2:32 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta (603,550). |
3736 | NUM 3:43 | Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273). |
3739 | NUM 3:46 | Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Israẹli tó ju iye àwọn ọmọ Lefi lọ, |
3743 | NUM 3:50 | Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùndínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli. |
3784 | NUM 4:40 | Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n (2,630). |
3788 | NUM 4:44 | Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200). |
4498 | NUM 26:7 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730). |
4516 | NUM 26:25 | Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (64,300). |
4528 | NUM 26:37 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. |
4538 | NUM 26:47 | Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). |
4542 | NUM 26:51 | Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀sán dín làádọ́rin (601,730). |
4553 | NUM 26:62 | Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn. |
4701 | NUM 31:35 | pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún (32,000), ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí. |
4702 | NUM 31:36 | Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́: ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn. |
4704 | NUM 31:38 | ẹgbọrọ màlúù jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún (36,000), tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàádọ́rin (72); |
4705 | NUM 31:39 | kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500), tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta (61). |
4706 | NUM 31:40 | Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n (32). |
4709 | NUM 31:43 | Ààbọ̀ tí ìjọ jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn, |
4710 | NUM 31:44 | pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) màlúù |
4711 | NUM 31:45 | tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500). |
4801 | NUM 33:39 | Aaroni jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta (123) ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hori. |
5981 | JOS 7:3 | Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.” |
5982 | JOS 7:4 | Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá. |
6007 | JOS 8:3 | Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru. |
6702 | JDG 7:6 | Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi. |
6703 | JDG 7:7 | Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” |
6704 | JDG 7:8 | Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà. |
6712 | JDG 7:16 | Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà. |
6718 | JDG 7:22 | Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati. |
6725 | JDG 8:4 | Gideoni àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀síwájú láti lépa àwọn ọ̀tá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jordani wọ́n sì kọjá sí òdìkejì. |
6857 | JDG 11:26 | Fún ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà? |
6935 | JDG 15:4 | Samsoni sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjì méjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀. |
6942 | JDG 15:11 | Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Etamu, wọ́n sì sọ fún Samsoni pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Filistini ní ń ṣe alákòóso lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?” Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.” |
6978 | JDG 16:27 | Ní àsìkò náà, tẹmpili yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Filistini wà níbẹ̀, ní òkè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Samsoni bí òun ti ń ṣeré. |
7309 | 1SA 4:10 | Nígbà náà àwọn Filistini jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Israẹli olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn ará Israẹli tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọmọ-ogun orí ilẹ̀. |
7455 | 1SA 11:8 | Nígbà tí Saulu sì kó wọn jọ ní Beseki, àwọn ọkùnrin Israẹli tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000), àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000). |
7489 | 1SA 13:2 | Saulu yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn. |
7492 | 1SA 13:5 | Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) kẹ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. |
7844 | 1SA 24:3 | Saulu sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó. |
7866 | 1SA 25:2 | Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. |
7910 | 1SA 26:2 | Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi. |
8083 | 2SA 2:31 | Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjìdínnírinwó (360) ènìyàn. |
8161 | 2SA 6:1 | Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000). |
8599 | 2SA 21:16 | Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi. |
8674 | 2SA 23:18 | Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. |
8879 | 1KI 5:12 | Ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005). |
8894 | 1KI 5:27 | Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ènìyàn. |
8897 | 1KI 5:30 | àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà. |
9099 | 1KI 10:17 | Ó sì túnṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) asà wúrà lílù, pẹ̀lú òsùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí asà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lebanoni. |
9114 | 1KI 11:3 | Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà. |
9426 | 1KI 20:15 | Nígbà náà ni Ahabu ka àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232). Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tókù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000). |
9427 | 1KI 20:16 | Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́. |
10042 | 2KI 18:14 | Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah ọba Juda sì ránṣẹ́ yìí sí ọba Asiria ní Lakiṣi, wí pé, “Mo ti ṣẹ̀, padà lẹ́yìn mi: èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba Asiria sì bu fún Hesekiah ọba Juda ọ̀ọ́dúnrún (300) tálẹ́ǹtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ǹtì wúrà. |
10543 | 1CH 7:4 | Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (36,000) tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó. |
10546 | 1CH 7:7 | Àwọn ọmọ Bela: Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (22,034) ènìyàn. |
10688 | 1CH 11:11 | Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi: Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan. |
10697 | 1CH 11:20 | Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta. |
10752 | 1CH 12:28 | pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (3,700) ènìyàn, |
10754 | 1CH 12:30 | àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà; |
10759 | 1CH 12:35 | Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000). Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn. |
10919 | 1CH 19:7 | Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Maaka pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Medeba, nígbà tí àwọn ará Ammoni kójọpọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun. |
10991 | 1CH 23:3 | Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000). |
11173 | 1CH 29:4 | ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ǹtì wúrà, ti wúrà Ofiri àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà. |
11218 | 2CH 2:1 | Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn. |
11233 | 2CH 2:16 | Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n (153,600). |
11234 | 2CH 2:17 | Ó sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún (3,600) alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́. |
11256 | 2CH 4:5 | Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) bati dúró. |