Wildebeest analysis examples for:   yor-yor   9    February 11, 2023 at 20:00    Script wb_pprint_html.py   by Ulf Hermjakob

111  GEN 5:5  Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú.
114  GEN 5:8  Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.
117  GEN 5:11  Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú.
120  GEN 5:14  Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú.
123  GEN 5:17  Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú.
126  GEN 5:20  Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú.
133  GEN 5:27  Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.
136  GEN 5:30  Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
235  GEN 9:29  Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín làádọ́ta (950), ó sì kú.
286  GEN 11:19  Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
3478  LEV 25:8  “ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta (49) ni kí ẹ kà.
3628  NUM 1:23  Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300).
3672  NUM 2:13  Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje (59,300).
6604  JDG 4:3  Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.
6614  JDG 4:13  Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni.
7314  1SA 4:15  Eli sì di ẹni méjìdínlọ́gọ́run (98) ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́.
10625  1CH 9:6  Ní ti ará Sera: Jeueli. Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
10628  1CH 9:9  Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
12030  EZR 1:9  Èyí ni iye wọn. Ọgbọ̀n àwo wúrà 30 Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000 Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n 29
12040  EZR 2:8  Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún (945)
12048  EZR 2:16  Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́run (98)
12052  EZR 2:20  Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95).
12068  EZR 2:36  Àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje (973)
12074  EZR 2:42  Àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàndínlógóje (139).
12090  EZR 2:58  Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).
12446  NEH 7:21  Ateri (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98)
12450  NEH 7:25  Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95).
12463  NEH 7:38  Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin (3,930).
12464  NEH 7:39  Àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje (973)
12485  NEH 7:60  Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).
12600  NEH 11:8  àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.
20603  EZK 4:5  Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).
20607  EZK 4:9  “Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).
22161  DAN 12:11  “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).
25695  LUK 16:6  “Ó sì wí pé, ‘Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) òsùwọ̀n òróró.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta lé ní irinwó (450).’