42 | GEN 2:11 | Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. |
138 | GEN 5:32 | Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti. |
148 | GEN 6:10 | Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti. |
173 | GEN 7:13 | Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. |
224 | GEN 9:18 | Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.) |
228 | GEN 9:22 | Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. |
236 | GEN 10:1 | Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi. |
241 | GEN 10:6 | Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani. |
242 | GEN 10:7 | Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani. |
250 | GEN 10:15 | Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti. |
252 | GEN 10:17 | àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, |
253 | GEN 10:18 | àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀. |
255 | GEN 10:20 | Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn. |
258 | GEN 10:23 | Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki. |
261 | GEN 10:26 | Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. |
262 | GEN 10:27 | Hadoramu, Usali, Dikla, |
264 | GEN 10:29 | Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani. |
293 | GEN 11:26 | Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani. |
294 | GEN 11:27 | Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti. |
295 | GEN 11:28 | Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. |
296 | GEN 11:29 | Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. |
298 | GEN 11:31 | Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀. |
299 | GEN 11:32 | Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani. |
303 | GEN 12:4 | Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. |
304 | GEN 12:5 | Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀. |
337 | GEN 13:18 | Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa. |
342 | GEN 14:5 | Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu, |
343 | GEN 14:6 | àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù. |
344 | GEN 14:7 | Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (ti o túmọ̀ sí Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú. |
350 | GEN 14:13 | Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Abramu, ará Heberu ni. Abramu sá ti tẹ̀dó sí ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre ará Amori, arákùnrin Eṣkolu àti Aneri: àwọn ẹni tí ó ń bá Abramu ní àṣepọ̀. |
352 | GEN 14:15 | Ní ọ̀gànjọ́ òru, Abramu pín àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Hoba tí ó wà ní apá òsì Damasku. |
381 | GEN 15:20 | àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. |
383 | GEN 16:1 | Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. |
385 | GEN 16:3 | Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya. |
386 | GEN 16:4 | Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀. |
388 | GEN 16:6 | Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ. |
389 | GEN 16:7 | Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. |
390 | GEN 16:8 | Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?” Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.” |
397 | GEN 16:15 | Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli. |
398 | GEN 16:16 | Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un. |
523 | GEN 21:9 | Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, |
528 | GEN 21:14 | Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Hagari, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Beerṣeba. |
531 | GEN 21:17 | Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí. |
533 | GEN 21:19 | Ọlọ́run sì ṣí ojú Hagari, ó sì rí kànga kan, ó lọ síbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu. |
570 | GEN 22:22 | Kesedi, Haso, Pildasi, Jidlafi, àti Betueli.” |
574 | GEN 23:2 | Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara. |
575 | GEN 23:3 | Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé, |
577 | GEN 23:5 | Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé, |
579 | GEN 23:7 | Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti. |
582 | GEN 23:10 | Efroni ará Hiti sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Abrahamu lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú, |
588 | GEN 23:16 | Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò. |
590 | GEN 23:18 | bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà. |
591 | GEN 23:19 | Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani. |
592 | GEN 23:20 | Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un. |
663 | GEN 25:4 | Àwọn ọmọ Midiani ni Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura. |
668 | GEN 25:9 | Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki àti Iṣmaeli sì sin ín sínú ihò àpáta ni Makpela ní ẹ̀gbẹ́ Mamre, ní oko Efroni ọmọ Sohari ará Hiti, |
669 | GEN 25:10 | inú oko tí Abrahamu rà lọ́wọ́ ara Hiti yìí ni a sin Abrahamu àti Sara aya rẹ̀ sí. |
671 | GEN 25:12 | Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un. |
674 | GEN 25:15 | Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema. |
677 | GEN 25:18 | Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo. |
727 | GEN 26:34 | Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti. |
771 | GEN 27:43 | Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ, sálọ sọ́dọ̀ Labani ẹ̀gbọ́n mi ní Harani. |
774 | GEN 27:46 | Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.” |
784 | GEN 28:10 | Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. |
800 | GEN 29:4 | Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” |
980 | GEN 33:19 | Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori tí í ṣe baba Ṣekemu. |
983 | GEN 34:2 | Nígbà tí Ṣekemu ọmọ ọba Hamori ará Hifi rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀. |
985 | GEN 34:4 | Ṣekemu sì wí fún Hamori baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.” |
987 | GEN 34:6 | Hamori baba Ṣekemu sì jáde wá láti bá Jakọbu sọ̀rọ̀. |
989 | GEN 34:8 | Hamori sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣekemu fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya. |
994 | GEN 34:13 | Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́. |
999 | GEN 34:18 | Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. |
1001 | GEN 34:20 | Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀. |
1005 | GEN 34:24 | Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà. |
1007 | GEN 34:26 | Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde. |
1039 | GEN 35:27 | Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre nítòsí i Kiriati-Arba (ti o túmọ̀ sí Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. |
1043 | GEN 36:2 | Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. |
1061 | GEN 36:20 | Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, |
1062 | GEN 36:21 | Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu. |
1063 | GEN 36:22 | Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani. |
1067 | GEN 36:26 | Àwọn ọmọ Diṣoni ni: Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani. |
1070 | GEN 36:29 | Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, |
1071 | GEN 36:30 | Diṣoni Eseri, àti Diṣani. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri. |
1075 | GEN 36:34 | Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. |
1076 | GEN 36:35 | Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. |
1077 | GEN 36:36 | Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. |
1079 | GEN 36:38 | Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀. |
1080 | GEN 36:39 | Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. |
1098 | GEN 37:14 | O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti àfonífojì Hebroni. Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu, |
1117 | GEN 37:33 | Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” |
1121 | GEN 38:1 | Ní àkókò náà, Juda lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Adullamu kan tí ń jẹ́ Hira. |
1132 | GEN 38:12 | Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ. |
1164 | GEN 39:14 | ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. |
1167 | GEN 39:17 | Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. |
1188 | GEN 40:15 | Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.” |