8514 | 2SA 19:1 | Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Absalomu! Ọmọ mi, ọmọ mí Absalomu! Á à! Ìbá ṣe pé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” |
8518 | 2SA 19:5 | Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” |
17728 | ISA 1:4 | Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i. |
17748 | ISA 1:24 | Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi. |
18619 | ISA 44:16 | Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.” |
21155 | EZK 25:3 | Sì wí fún àwọn ará Ammoni pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè tí ó wí pé. Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn, |
24859 | MRK 14:36 | Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.” |
28199 | ROM 8:15 | Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” |
29204 | GAL 4:6 | Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” |