33 | GEN 2:2 | Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. |
47 | GEN 2:16 | Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; |
50 | GEN 2:19 | Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. |
52 | GEN 2:21 | Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. |
54 | GEN 2:23 | Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” |
63 | GEN 3:7 | Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn. |
71 | GEN 3:15 | Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.” |
72 | GEN 3:16 | Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé, “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.” |
73 | GEN 3:17 | Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. |
75 | GEN 3:19 | Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.” |
88 | GEN 4:8 | Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á. |
103 | GEN 4:23 | Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. |
113 | GEN 5:7 | Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. |
130 | GEN 5:24 | Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ. |
142 | GEN 6:4 | Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà. |
194 | GEN 8:10 | Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. |
197 | GEN 8:13 | Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. |
205 | GEN 8:21 | Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. |
208 | GEN 9:2 | Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. |
211 | GEN 9:5 | Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn. |
244 | GEN 10:9 | Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.” |
260 | GEN 10:25 | Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani. |
301 | GEN 12:2 | “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì bùkún fún ọ; èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí. |
302 | GEN 12:3 | Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.” |
321 | GEN 13:2 | Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà. |
348 | GEN 14:11 | Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ. |
411 | GEN 17:13 | Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. |
435 | GEN 18:10 | Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. |
497 | GEN 20:1 | Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀. |
583 | GEN 23:11 | pé, “Rárá, olúwa mi. Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.” |
604 | GEN 24:12 | Ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Abrahamu olúwa mi. |
621 | GEN 24:29 | Rebeka ní arákùnrin tí ń jẹ́ Labani; Labani sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò. |
652 | GEN 24:60 | Wọ́n sì súre fún Rebeka, wọn sì wí fun un pé, “Ìwọ ni arábìnrin wa ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó ni ẹnu ibodè ọ̀tá wọn.” |
659 | GEN 24:67 | Nígbà náà ni Isaaki mú Rebeka wọ inú àgọ́ ìyá rẹ̀, Sara, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Isaaki lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀. |
682 | GEN 25:23 | Olúwa sì wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ; àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” |
750 | GEN 27:22 | Jakọbu sì súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀. Isaaki sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jakọbu; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Esau.” |
791 | GEN 28:17 | Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.” |
837 | GEN 30:6 | Rakeli sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dani. |
882 | GEN 31:8 | Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran onítótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi onítótòtó. |
914 | GEN 31:40 | Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn. |
1022 | GEN 35:10 | Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu mọ́; bí kò ṣe Israẹli.” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli. |
1122 | GEN 38:2 | Juda sì pàdé ọmọbìnrin Kenaani kan níbẹ̀ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua. Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lòpọ̀; |
1148 | GEN 38:28 | Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.” |
1245 | GEN 41:49 | Josẹfu pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí iyanrìn Òkun; ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà. |
1307 | GEN 43:16 | Nígbà tí Josẹfu rí Benjamini pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì ṣe àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.” |
1314 | GEN 43:23 | Ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà ni fún yín, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìṣúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Simeoni jáde tọ̀ wọ́n wá. |
1476 | GEN 49:2 | “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu; ẹ fetí sí Israẹli baba yín. |
1494 | GEN 49:20 | “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára; yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba. |
1501 | GEN 49:27 | “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú; ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ, ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.” |
1527 | GEN 50:20 | Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là. |
1535 | EXO 1:2 | Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda; |
1536 | EXO 1:3 | Isakari, Sebuluni àti Benjamini; |
1537 | EXO 1:4 | Dani àti Naftali; Gadi àti Aṣeri. |
1538 | EXO 1:5 | Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti. |
1547 | EXO 1:14 | Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò. |
1549 | EXO 1:16 | “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.” |
1550 | EXO 1:17 | Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè. |
1563 | EXO 2:8 | Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá. |
1588 | EXO 3:8 | Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. |
1595 | EXO 3:15 | Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’ “Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran. |
1596 | EXO 3:16 | “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. |
1597 | EXO 3:17 | Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’ |
1607 | EXO 4:5 | Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.” |
1625 | EXO 4:23 | mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ” |
1640 | EXO 5:7 | “Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì sísun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn. |
1657 | EXO 6:1 | Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Farao pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” |
1741 | EXO 8:26 | Nígbà náà ni Mose kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao, ó sì gbàdúrà sí Olúwa; |
1768 | EXO 9:25 | Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú. |
1770 | EXO 9:27 | Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo. |
1774 | EXO 9:31 | (A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi. |
1780 | EXO 10:2 | Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ ọmọ yín; bí mo ti jẹ àwọn ará Ejibiti ní yà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” |
1791 | EXO 10:13 | Nígbà náà ni Mose na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Ejibiti, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú wá; |
1793 | EXO 10:15 | Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. |
1799 | EXO 10:21 | Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí òkùnkùn bá à le bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti; àní òkùnkùn biribiri.” |
1831 | EXO 12:14 | “Ọjọ́ òní ni yóò sì máa ṣe ọjọ́ ìrántí fún yín, ẹ́yin yóò sì máa láàrín àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe ní àjọ fún Olúwa; ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. |
1833 | EXO 12:16 | Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; àti ní ọjọ́ keje àpéjọ mímọ́ mìíràn yóò wà fún yín. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, bí kò ṣe oúnjẹ tí olúkúlùkù yóò jẹ; kìkì èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe. |
1863 | EXO 12:46 | “Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́; ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé. Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀. |
1865 | EXO 12:48 | “Àjèjì ti ó bá ń gbé ní àárín yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ilà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ilà, wọ́n kò ni jẹ nínú rẹ̀. |
1873 | EXO 13:5 | Ní ìgbà tí Olúwa mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. |
1875 | EXO 13:7 | Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. |
1904 | EXO 14:14 | Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.” |
1907 | EXO 14:17 | Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. |
1909 | EXO 14:19 | Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn. |
1920 | EXO 14:30 | Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Israẹli là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti; Israẹli sì rí òkú àwọn ará Ejibiti ni etí òkun. |
1923 | EXO 15:2 | Olúwa ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. |
1926 | EXO 15:5 | Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta. |
1928 | EXO 15:7 | “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko. |
1929 | EXO 15:8 | Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun. |
1930 | EXO 15:9 | Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé, ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. èmi ó pín ìkógun; èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’ |
1965 | EXO 16:17 | Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré. |
1970 | EXO 16:22 | Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń kó tẹ́lẹ̀: òsùwọ̀n omeri méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mose. |
1972 | EXO 16:24 | Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin. |
1977 | EXO 16:29 | Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” |
1994 | EXO 17:10 | Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà. |
1996 | EXO 17:12 | Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose, wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. |
1998 | EXO 17:14 | Olúwa sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.” |
2003 | EXO 18:3 | Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ àkọ́bí ń jẹ́ Gerṣomu; nítorí Mose wí pé, “Èmi ń ṣe àlejò ni ilẹ̀ àjèjì.” |
2004 | EXO 18:4 | Èkejì ń jẹ́ Elieseri; ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.” |
2011 | EXO 18:11 | Mo mọ nísinsin yìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.” |
2013 | EXO 18:13 | Ní ọjọ́ kejì, Mose jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mose fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. |