10050 | 2KI 18:22 | Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Hesekiah mú kúrò, tí ó wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jerusalẹmu”? |
14065 | PSA 10:13 | Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀, “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”? |
17033 | PRO 20:9 | Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”? |
17395 | ECC 1:10 | Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé, “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”? Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́, o ti wà ṣáájú tiwa. |
18279 | ISA 29:16 | Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé, “Òun kọ́ ló ṣe mí”? Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, “Kò mọ nǹkan”? |
18407 | ISA 36:7 | Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”? |
18517 | ISA 40:27 | Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu? Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli, “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa; ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”? |
23718 | MAT 15:16 | Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”? |
28885 | 2CO 1:17 | Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”? |
30035 | HEB 1:5 | Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ”? Àti pẹ̀lú pé, “Èmi yóò jẹ́ baba fún un, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”? |
30043 | HEB 1:13 | Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”? |